1 Samuel 17:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Filistini kó ara wọn jọ sí Soko, ìlú kan ní ilẹ̀ Juda láti bá Israẹli jagun. Wọ́n pa ibùdó wọn sí Efesi Damimu, tí ó wà láàrin Soko ati Aseka.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
AWỌN Filistini si gbá ogun wọn jọ si oju ijà, nwọn si gba ara wọn jọ si Ṣoko, ti iṣe ti Juda, nwọn si do si Ṣoko ati Aseka, ni Efesdammimi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fílístínì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ fún ogun ní Síkọ̀ ti Júdà. Wọ́n pàgọ́ sí Efesidámímù, láàárin Síkọ̀ àti Ásékà,