1 Samuel 17:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn mẹta tí wọ́n dàgbà jùlọ láàrin àwọn ọmọ Jese bá Saulu lọ sójú ogun. Eliabu ni orúkọ àkọ́bí. Abinadabu ni ti ekeji, Ṣama sì ni ti ẹkẹta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn mẹta ti o dàgba ninu awọn ọmọ Jesse, si tọ Saulu lẹhin lọ si oju ijà: orukọ awọn ọmọ mẹtẹta ti o lọ si ibi ijà si ni Eliabu, akọbi, atẹle rẹ̀ si ni Abinadabu, ẹkẹta si ni Ṣamma.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ọmọ Jésè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tí ó ti dàgbà bá Ṣọ́ọ̀lù lọ sí ojú ogun: Èyí àkọ́bí ni Élíábù: Èyí èkejì ni Ábínádábù, èyí ẹ̀kẹta sì ní Ṣámínà.