1 Samuel 17:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Wọ́n ní, “Ẹ wo ọkunrin yìí, ẹ gbọ́ bí ó ti ń pe Israẹli níjà? Ọba sì ti sọ pé ẹni tí ó bá lè pa á yóo gba ẹ̀bùn lọpọlọpọ. Òun yóo sì fi ọmọbinrin òun fún olúwarẹ̀, ilé baba rẹ̀ yóo sì di òmìnira ní ilẹ̀ Israẹli: kò ní san owó orí mọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Israeli si wipe, Ẹnyin kò ri ọkunrin yi ti o goke wá ihin? lati pe Israeli ni ijà li o ṣe wá: yio si ṣe pe, ẹniti o ba pa ọkunrin na, ọba yio si fi ọrọ̀ pipọ fun u, yio si fun u li ọmọ rẹ̀ obinrin, yio si sọ ile baba rẹ di omnira ni Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì wí pé, “Ǹjẹ́ ẹ̀yin kò ríi bí ọkùnrin yìí ṣe ń jáde wá? Ó jáde wá láti pe Ísírẹ́lì níjà. Ọba yóò fún ọkùnrin tí ó bá pa á ní ọrọ̀ púpọ̀. Yóò tún fi ọmọ rẹ̀ obìnrin fún un ní ìyàwó, yóò sì sọ ilé e baba rẹ̀ di òmìnira kúrò nínú sísan owó orí ní Ísírẹ́lì.”