1 Samuel 17:26 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọkunrin náà pé, “Kí ni ọba ṣe ìlérí pé òun ó fún ẹni tí ó bá pa Filistini yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Israẹli? Ta ni aláìkọlà Filistini yìí tí ń pẹ̀gàn àwọn ọmọ ogun Ọlọrun alààyè?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si wi fun awọn ọkunrin ti o duro li ọdọ rẹ̀ pe, Kili a o ṣe fun ọkunrin na ti o ba pa Filistini yi, ti o si mu ẹgàn na kuro li ara Israeli? tali alaikọla Filistini yi iṣe, ti yio fi ma gan ogun Ọlọrun alãye?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin tí ó dúró ní ẹ̀gbẹ́ ẹ rẹ̀ pé, “Kí ni a ó ò ṣe fún ọkùnrin náà tí ó bá pa Fílístínì yìí, tí ó sì mú ẹ̀gàn kúrò lára Ísírẹ́lì? Ta ni aláìkọlà Fílístínì tí ó jẹ́ wí pé yóò máa gan ogun Ọlọ́run alààyè?”