1 Samuel 17:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Eliabu, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ àgbà gbọ́ tí ó ń bá àwọn ọkunrin náà sọ̀rọ̀, ó bínú sí Dafidi, ó ní, “Kí ni ìwọ ń wá níbí? Ta ni ó ń tọ́jú àwọn aguntan rẹ ninu pápá? Ìwọ onigbeeraga ati ọlọ́kàn líle yìí, nítorí kí o lè wo ogun ni o ṣe wá síbí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eliabu ẹgbọn rẹ̀ si gbọ́ nigbati on ba awọn ọkunrin na sọ̀rọ; Eliabu si binu si Dafidi, o si wipe, Ẽ ti ṣe ti iwọ fi sọkalẹ wá ihinyi, tani iwọ ha fi agutan diẹ nì le lọwọ́ li aginju? emi mọ̀ igberaga rẹ, ati buburu ọkàn rẹ; nitori lati ri ogun ni iwọ ṣe sọkalẹ wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Élíábù ẹ̀gbọ́n Dáfídì gbọ́ nígbà tí ó ń bá ọkùnrin yìí sọ̀rọ̀, ó bínú sí i, ó sì wí pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ fi sọ̀kalẹ̀ wá síbí? Àti pé ta ni ìwọ fi àwọn àgùntàn kékeré tó kù ṣọ́ ní ihà? Èmi mọ ìgbéraga rẹ, àti búburú ọkàn rẹ: ìwọ sọ̀kalẹ̀ wá nìkan láti wòran ogun.”