1 Samuel 17:39 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi di idà Saulu mọ́ ihamọra náà, ó sì gbìyànjú láti rìn, ṣugbọn kò lè rìn nítorí pé kò wọ ihamọra ogun rí. Dafidi sọ fún Saulu pé, “N kò lè lo ihamọra yìí, nítorí pé n kò wọ̀ ọ́ rí.” Dafidi bá tú wọn kúrò lára rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si di ida rẹ̀ mọ ihamọra rẹ̀, on si gbiyanju lati lọ, on kò sa iti dan a wò. Dafidi si wi fun Saulu pe, Emi kò le ru wọnyi lọ, nitoripe emi kò idan a wò. Dafidi si tu wọn kuro li ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì si di idà rẹ̀ mọ́ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní rìn káàkiri nítorí wí pé kò mọ́ ọ lára. Ó sọ fún Ṣọ́ọ̀lù pé, “Èmi kò le wọ èyí lọ, kò mọ́ mi lára.” Ó sì bọ́ wọn kúrò.