1 Samuel 17:40 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó mú ọ̀pá darandaran rẹ̀, ó ṣa òkúta marun-un tí ń dán ninu odò, ó kó wọn sinu àpò rẹ̀, ó mú kànnàkànnà rẹ̀ lọ́wọ́, ó sì lọ bá Filistini náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si mu ọpa rẹ̀ li ọwọ́ rẹ̀, o si ṣà okuta marun ti o jọlọ̀ ninu odò, o si fi wọn sinu apò oluṣọ agutan ti o ni, ani sinu asùwọn: kànakana rẹ̀ si wà li ọwọ́ rẹ̀; o si sunmọ Filistini na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, ó sì mú ọ̀pá a rẹ̀ lọ́wọ́, ó ṣa òkúta dídán márùn ún létí odò, ó kó wọn sí àpò olùṣọ́ àgùntàn tí ó wà lọ́wọ́ ọ rẹ̀ pẹ̀lú kànnàkànnà.