1 Samuel 17:46 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lónìí yìí ni OLUWA yóo fà ọ́ lé mi lọ́wọ́, n óo pa ọ́, n óo gé orí rẹ, n óo sì fi òkú àwọn ọmọ ogun Filistini fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ati ẹranko ìgbẹ́. Gbogbo ayé yóo sì mọ̀ pé Ọlọrun wà fún Israẹli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Loni yi li Oluwa yio fi iwọ le mi lọwọ́, emi o pa ọ, emi o si ke ori rẹ kuro li ara rẹ; emi o si fi okú ogun Filistini fun ẹiyẹ oju ọrun loni yi, ati fun ẹranko igbẹ; gbogbo aiye yio si mọ̀ pe, Ọlọrun wà fun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lónìí yìí ni OLÚWA yóò fi ọ́ lé mi lọ́wọ́, èmi yóò sì pa ọ́, èmi yóò sì gé orí ì rẹ. Lónìí èmi yóò fi òkú ogun Fílístínì fún ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ìgbó, gbogbo ayé yóò sì mọ̀ pé Ọlọ́run wà ní Ísírẹ́lì.