1 Samuel 17:47 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn eniyan wọnyi yóo sì mọ̀ dájú pé OLUWA kò nílò idà ati ọ̀kọ̀ láti gba eniyan là. Ti OLUWA ni ogun yìí, yóo sì gbé mi borí rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ijọ enia yio si mọ̀ daju pe, Oluwa kò fi ida on ọ̀kọ gbà ni la: nitoripe ogun na ti Oluwa ni, yio si fi ọ le wa lọwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gbogbo àwọn tí ó péjọ níbí ni yóò mọ̀ pé kì í ṣe nípa ọ̀kọ̀ tàbí idà ni OLÚWA fi ń gbàlà; ogun náà ti OLÚWA ni, yóò sì fi gbogbo yín lé ọwọ́ ọ wa.”