1 Samuel 17:51 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi sáré sí Goliati, ó yọ idà Goliati kúrò ninu àkọ̀, ó sì fi gé orí rẹ̀. Nígbà tí àwọn ọmọ ogun Filistini rí i pé akikanju àwọn ti kú, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si sure, o si duro lori Filistini na, o si mu ida rẹ̀, o si fà a yọ ninu akọ̀ rẹ̀, o si pa a, o si fi idà na bẹ́ ẹ li ori. Nigbati awọn Filistini si ri pe akikanju wọn kú, nwọn si sa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Dáfídì sì sáré ó sì dúró lórí rẹ̀. Ó sì mú idà Fílístínì, ó sì fà á yọ nínú àkọ̀ ọ rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti pa á tan, ó sì gé orí i rẹ̀ pẹ̀lú idà. Nígbà tí àwọn ará Fílístínì rí i wí pé akọni wọn ti kú, wọ́n yípadà wọ́n sì sálọ.