1 Samuel 17:52 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn ọmọ ogun Israẹli ati ti Juda hó ìhó ogun, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn Filistini lọ. Wọ́n lé wọn títí dé Gati ati dé ẹnu ibodè Ekironi. Àwọn Filistini tí wọ́n fara gbọgbẹ́ sì ṣubú láti Ṣaaraimu títí dé Gati ati Ekironi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọkunrin Israeli ati ti Juda si dide, nwọn si ho yè, nwọn si nle awọn Filistini lọ, titi nwọn fi de afonifoji kan, ati si ojubode Ekronu. Awọn ti o gbọgbẹ ninu awọn Filistini si ṣubu lulẹ li ọ̀na Ṣaaraimu, ati titi de Gati, ati Ekronu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà, àwọn ọkùnrin Ísírẹ́lì àti ti Júdà súnmọ́ iwájú pẹ̀lú ariwo, wọ́n sì lépa àwọn ará Fílístínì dé ẹnu ibodè Gátì àti títí dé ẹnu ibodè Ékírónì. Àwọn tí ó kú wà káàkiri ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà Ṣáráímù àti títí dé ọ̀nà Gátì àti Ékírónì.