1 Samuel 17:55 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Saulu rí Dafidi tí ó ń lọ bá Goliati jà, ó bèèrè lọ́wọ́ Abineri, olórí ogun rẹ̀ pé, “Ọmọ ta ni ọmọkunrin yìí?” Abineri dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, n kò mọ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati Saulu si ri Dafidi ti nlọ pade Filistini na, o si bi Abneri oloriogun pe, Abneri, ọmọ tani ọmọde yi iṣe? Abneri si dahun pe, bi ọkàn rẹ ti wà lãye, ọba, emi kò mọ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Ṣọ́ọ̀lù sì ti wo Dáfídì bí ó ṣe ń jáde lọ pàdé Fílístínì, ó wí fún Ábínérì, olórí àwọn ológun rẹ̀ pé, “Ábínérì, ọmọ ta ni ọmọdékùnrin yìí?” Ábínérì dáhùn pe, “Bí ọkàn rẹ̀ ti ń bẹ ní ààyè, ọba èmi kò mọ̀.”