1 Samuel 17:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Goliati dúró, ó sì kígbe pe àwọn ọmọ Israẹli, ó ní, “Kí ló dé tí ẹ fi kó ara yín jọ láti jagun? Ṣebí Filistini kan ni èmi, ẹ̀yin náà sì jẹ́ ẹrú Saulu? Ẹ̀yin ẹ yan ọkunrin kan láàrin yín tí yóo sọ̀kalẹ̀ wá bá mi jà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si duro o si kigbe si ogun Israeli, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin jade lati tẹgun? ṣe Filistini kan li emi iṣe? ẹnyin si jẹ ẹrú Saulu. Ẹnyin yan ọkunrin kan fun ara nyin, ki ẹnyin si jẹ ki o sọkale tọ̀ mi wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Gòláyátì dìde, ó sì kígbe sí ogun Ísírẹ́lì pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi jáde wá, tí ẹ ṣe tò fún ogun? Ṣé èmi kì í ṣe Fílístínì ni, àbí ẹ̀yin kì í ṣe ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù? Yan ọkùnrin kan kí o sì jẹ́ kí ó sọ̀kalẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ mi.