1 Samuel 18:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn tí Dafidi ati Saulu parí ọ̀rọ̀ wọn, ọkàn Jonatani, ọmọ Saulu fà mọ́ Dafidi lọpọlọpọ ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ara rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, nigbati o ba Saulu sọ̀rọ tan, ọkàn Jonatani si fà mọ ọkàn Dafidi, Jonatani si fẹ ẹ bi ontikararẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń bá Ṣọ́ọ̀lù sọ, ọkàn Jónátanì di ọ̀kan pẹ̀lú ti Dáfídì, ó sì fẹ́ràn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀.