1 Samuel 18:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keji, ẹ̀mí burúkú láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun bà lé Saulu, ó sì ń sọ kántankàntan láàrin ilé rẹ̀. Dafidi bẹ̀rẹ̀ sí ta hapu fún un gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ọ̀kọ̀ kan wà lọ́wọ́ Saulu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe ni ijọ keji, ti ẹmi buburu lati ọdọ Ọlọrun wá si ba le Saulu, on si sọtẹlẹ li arin ile; Dafidi si fi ọwọ́ rẹ̀ ṣire lara duru bi igba atẹhinwa; ẹṣín kan mbẹ lọwọ Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kejì ẹ̀mí búburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá pẹ̀lú agbára sórí Ṣọ́ọ̀lù, ó sì sọ àṣọtẹ́lẹ̀ ní ilé rẹ̀ nígbà tí Dáfídì sì ń fọn ohun èlò orin olókùn, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe láti ẹ̀yìn wá, Ṣọ́ọ̀lù sì ní ọ̀kọ̀ kan ní ọwọ́ rẹ̀.