1 Samuel 18:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu sọ fún Dafidi pé, “Merabu ọmọbinrin mi àgbà nìyí, n óo fún ọ kí o fi ṣe aya, ṣugbọn o óo jẹ́ ọmọ ogun mi, o óo sì máa ja ogun OLUWA.” Nítorí Saulu rò ninu ara rẹ̀ pé, àwọn Filistini ni yóo pa Dafidi, òun kò ní fi ọwọ́ ara òun pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wi fun Dafidi pe, Wo Merabu ọmọbinrin mi, eyi agbà, on li emi o fi fun ọ li aya: ṣugbọn ki iwọ ki o ṣe alagbara fun mi, ki o si ma ja ija Oluwa. Nitoriti Saulu ti wi bayi pe, Màṣe jẹ ki ọwọ́ mi ki o wà li ara rẹ̀; ṣugbọn jẹ ki ọwọ́ awọn Filistini ki o wà li ara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù wí fún Dáfídì pé, “Èyí ni àgbà nínú àwọn ọmọbìnrin mi Mérábù. Èmi yóò fi òun fún ọ ní aya. Kí ìwọ sìn mí bí akọni, kí o sì máa ja ogun OLÚWA.” Nítorí tí Ṣọ́ọ̀lù wí fún ara rẹ̀ pé, “Èmi kì yóò gbé ọwọ́ mi sókè síi. Jẹ́ kí àwọn Fílístínì ṣe èyí.”