1 Samuel 18:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu pàṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀ pé, “Ẹ lọ bá Dafidi sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀ pé, inú ọba dùn sí i lọpọlọpọ, ati pé gbogbo àwọn iranṣẹ ọba fẹ́ràn rẹ̀, nítorí náà ó yẹ kí ó fẹ́ ọmọ ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si paṣẹ fun awọn iranṣẹ rẹ̀ pe, Ẹ lọ ba Dafidi sọ̀rọ kẹlẹkẹlẹ pe, Kiyesi i, inu ọba dùn si ọ jọjọ, ati gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀ li o si fẹ ọ, njẹ nitorina jẹ ana ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ sọ fún Dáfídì ní ìkọ̀kọ̀, kí ẹ sì wí pé, ‘Wò ó, inú ọba dùn sí ọ, gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni ó fẹ́ràn rẹ, nísinsìn yìí jẹ́ àna ọba.’ ”