1 Samuel 18:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí wọ́n sọ èyí fún Dafidi, ó dá wọn lóhùn pé, “Kì í ṣe nǹkan kékeré ni láti jẹ́ àna ọba, talaka ni mí, èmi kì í sì í ṣe eniyan pataki.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn iranṣẹ Saulu si sọ̀rọ wọnni li eti Dafidi. Dafidi si wipe, O ha ṣe nkan ti o fẹrẹ loju nyin lati jẹ ana ọba? Talaka li emi ati ẹni ti a kò kà si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n tún ọ̀rọ̀ náà sọ fún Dáfídì. Ṣùgbọ́n Dáfídì wí pé, “Ṣé ẹ rò pé ohun kékeré ni láti jẹ́ àna ọba? Mo jẹ́ tálákà ènìyàn àti onímọ̀ kékeré.”