1 Samuel 18:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Saulu sì rán wọn pé kí wọ́n sọ fún Dafidi pé, “Ọba kò bèèrè ẹ̀bùn igbeyawo kankan lọ́wọ́ rẹ ju ọgọrun-un awọ orí adọ̀dọ́ àwọn ará Filistia, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san lára àwọn ọ̀tá ọba.” Saulu rò pé àwọn ará Filistia yóo tipa bẹ́ẹ̀ pa Dafidi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si wipe, Bayi li ẹnyin o sọ fun Dafidi, ọba kò sa fẹ ohun-ana kan bikoṣe ọgọrun ẹfa abẹ Filistini, ati lati gbẹsan lara awọn ọta ọba; ṣugbọn Saulu rò ikú Dafidi lati ọwọ́ awọn Filistini wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù dáhùn pé, “Sọ fún Dáfídì pé, ‘Ọba kò fẹ́ owó orí láti ọ̀dọ̀ àna rẹ̀ ju awọ iwájú orí ọgọ́rùn ún Fílístínì lọ láti fi gba ẹ̀san lórí àwọn ọ̀ta rẹ̀.’ ” Èrò Ṣọ́ọ̀lù ni wí pé kí Dáfídì ṣubú sí ọwọ́ àwọn ará Fílístínì.