1 Samuel 18:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ninu gbogbo ogun tí wọ́n bá àwọn ara Filistia jà, Dafidi ní ìṣẹ́gun ju gbogbo àwọn olórí ogun Saulu yòókù lọ. Ó sì jẹ́ olókìkí láàrin wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ-alade Filistini si jade lọ: o si ṣe, lẹhin igbati nwọn lọ, Dafidi si huwa ọlọgbọ́n ju gbogbo awọn iranṣẹ Saulu lọ; orukọ rẹ̀ si ni iyìn jọjọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn olórí ogun Fílístínì tún tẹ̀ṣíwájú láti lọ sí ogun, ó sì ṣe lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n lọ, Dáfídì ṣe àṣeyọrí ju gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ṣọ́ọ̀lù lọ, orúkọ rẹ̀ sì gbilẹ̀.