1 Samuel 18:5 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi ń ṣe àṣeyọrí ninu àwọn iṣẹ́ tí Saulu ń rán an. Nítorí náà, Saulu fi ṣe ọ̀kan ninu àwọn olórí ogun rẹ̀. Èyí sì tẹ́ àwọn olórí yòókù lọ́rùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi a si ma lọ si ibikibi ti Saulu rán a, a ma huwa ọlọgbọ́n: Saulu si fi i jẹ olori ogun, o si dara loju gbogbo awọn enia, ati pẹlupẹlu loju awọn iranṣẹ Saulu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohunkóhun tí Ṣọ́ọ̀lù bá rán an láti ṣe, Dáfídì máa ṣe ní àṣeyọrí, Ṣọ́ọ̀lù náà sì fun un ní ipò tí ó ga jù láàrin àwọn ológun. Eléyìí sì tẹ́ gbogbo ènìyàn lọ́rùn, àti pẹ̀lú ó sì tẹ́ àwọn ìjòyè Ṣọ́ọ̀lù lọ́rùn pẹ̀lú.