1 Samuel 18:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí wọ́n ti ń pada bọ̀ wálé, lẹ́yìn tí Dafidi ti pa Goliati, àwọn obinrin jáde láti gbogbo ìlú Israẹli, wọ́n lọ pàdé Saulu ọba, pẹlu orin ati ijó, wọ́n ń lu aro, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀ pẹlu àwọn ohun èlò orin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, bi nwọn ti de, nigbati Dafidi ti ibi ti o gbe pa Filistini na bọ̀, awọn obinrin si ti gbogbo ilu Israeli jade wá, nwọn nkọrin nwọn si njo lati wá ipade Saulu ọba, ti awọn ti ilù, ati ayọ̀, ati duru.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn ènìyàn padà sí ilé lẹ́yìn ìgbà tí Dáfídì ti pa Fílístínì, gbogbo àwọn obìnrin tú jáde láti inú ìlú Ísírẹ́lì wá láti pàdé ọba Ṣọ́ọ̀lù pẹ̀lú orin àti ijó, pẹ̀lú orin ayọ̀ àti tamborínì àti ohun èlò orin.