1 Samuel 18:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Inú Saulu kò dùn sí orin tí wọ́n ń kọ, inú sì bí i gidigidi. Ó ní, “Wọ́n fún Dafidi ní ẹgbẹẹgbaarun ṣugbọn wọ́n fún mi ní ẹgbẹẹgbẹrun, kí ló kù tí wọn óo fún un ju ìjọba mi lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si binu gidigidi, ọ̀rọ na si buru loju rẹ̀ o si wipe, Nwọn fi ẹgbẹgbarun fun Dafidi, nwọn si fi ẹgbẹgbẹrun fun mi, kili o si kù fun u bikoṣe ijọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì bínú gidigidi, ọ̀rọ̀ náà sì korò létí rẹ̀ pé, “Wọ́n ti gbé ògo fún Dáfídì pẹ̀lú ẹgbẹgbàárún” ó sì wí pé, “Ṣùgbọ́n èmi pẹ̀lú ẹgbẹ̀rún kan. Kí ni ó kù kí ó gbà bí kò ṣe ìjọba?”