1 Samuel 19:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Saulu ju ọ̀kọ̀ náà, ó ní kí òun fi gún Dafidi mọ́ ògiri, ṣugbọn Dafidi yẹ̀ ẹ́, ọ̀kọ̀ náà wọ ara ògiri, Dafidi bá sá lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu ti nwá ọ̀na lati fi ẹṣín na gún Dafidi mọ ogiri: ṣugbọn on si yẹra kuro niwaju Saulu: o si sọ ẹṣín na wọnu ogiri: Dafidi si sa, o si fi ara pamọ li oru na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù sì wá ọ̀nà láti gún un mọ́ ògiri pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀, ṣùgbọ́n Dáfídì yẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ṣọ́ọ̀lù ti ju ọ̀kọ̀ náà mọ́ ara ògiri. Ní alẹ́ ọjọ́ náà Dáfídì sì fi ara pamọ́ dáradára.