1 Samuel 19:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní alẹ́ ọjọ́ náà, Saulu rán àwọn iranṣẹ kan láti máa ṣọ́ ilé Dafidi kí wọ́n lè pa á ní òwúrọ̀ ọjọ́ keji. Ṣugbọn Mikali iyawo rẹ̀ sọ fún Dafidi pé, “Sá àsálà fún ẹ̀mí rẹ ní alẹ́ yìí, nítorí pé bí o bá di ọ̀la níbí, wọn yóo pa ọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Saulu si rán onṣẹ si ile Dafidi, lati ma ṣọ ọ ati lati pa a li owurọ: Mikali aya Dafidi si wi fun u pe, Bi iwọ kò ba gbà ẹmi rẹ là li alẹ yi, li ọla li a o pa ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣọ́ọ̀lù rán ènìyàn sí ilé Dáfídì láti sọ́ ọ kí wọ́n sì pa á ní òwúrọ̀. Ṣùgbọ́n Míkálì, ìyàwó Dáfídì kìlọ̀ fún un pé, “Tí o kò bá sá fún ẹ̀mí ì rẹ ní alẹ́ yìí, ní ọ̀la ni a ó ò pa ọ́.”