1 Samuel 19:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi sá àsálà, ó sá lọ sí ọ̀dọ̀ Samuẹli ní Rama, ó sọ gbogbo ohun tí Saulu ti ṣe sí i fún un. Òun pẹlu Samuẹli sì lọ ń gbé Naioti.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si sa, o si bọ, o si tọ Samueli wá ni Rama, o si rò fun u gbogbo eyi ti Saulu ṣe si i. On ati Samueli si lọ, nwọn si ngbe Naoti.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí Dáfídì ti sá lọ tí ó sì ti bọ́, ó sì lọ sọ́dọ̀ Sámúẹ́lì ní Rámà ó sì sọ gbogbo ohun tí Ṣọ́ọ̀lù ti ṣe fún un. Òun àti Sámúẹ́lì lọ sí Náíótì láti dúró níbẹ̀.