1 Samuel 19:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Saulu gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn oníṣẹ́ rẹ̀, ó rán àwọn mìíràn, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ àsọtẹ́lẹ̀. Ó rán àwọn oníṣẹ́ ní ìgbà kẹta, àwọn náà tún ń sọ àsọtẹ́lẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A si ro fun Saulu, o si ran onṣẹ miran, awọn na si nsọtẹlẹ. Saulu si tun ran onṣẹ lẹ̃kẹta, awọn na si nsọtẹlẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì sọ fún Ṣọ́ọ̀lù nípa rẹ̀, ó sì rán ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mìíràn lọ àwọn náà sì ń ṣọtẹ́lẹ̀. Ṣọ́ọ̀lù tún rán oníṣẹ́ lọ ní ìgbà kẹta, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣọtẹ́lẹ̀.