1 Samuel 19:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bọ́ aṣọ rẹ̀, ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ níwájú Samuẹli. Ó sùn ní ìhòòhò ní ọ̀sán ati òru ọjọ́ náà. Àwọn eniyan sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ wí pé, “Àbí Saulu náà ti di wolii?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On si bọ aṣọ rẹ̀ silẹ, o si sọtẹlẹ pẹlu niwaju Samueli, o si dubulẹ nihoho ni gbogbo ọjọ na, ati ni gbogbo oru na. Nitorina nwọn si wipe, Saulu pẹlu ha wà ninu awọn woli?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó sì bọ́ aṣọ rẹ̀, òun pẹ̀lú sì ń ṣọtẹ́lẹ̀ níwájú Sámúẹ́lì. Ó sì dùbúlẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọjọ́ náà àti ní òru. Ìdí nìyìí tí àwọn ènìyàn fi wí pé, “Ṣé Ṣọ́ọ̀lù náà wà lára àwọn wòlíì ni?”