1 Samuel 19:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo dúró pẹlu baba mi ní orí pápá lọ́la níbi tí o bá farapamọ́ sí, n óo sì bá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ, ohunkohun tí mo bá sì gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, n óo sọ fún ọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si jade lọ, emi o si duro ti baba mi li oko na nibiti iwọ gbe wà, emi o si ba baba mi sọ̀rọ nitori rẹ; eyiti emi ba si ri, emi o sọ fun ọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò jáde lọ láti dúró ní ọ̀dọ̀ baba mi ní orí pápá níbi tí ó wà. Èmi yóò sọ̀rọ̀ fún un nípa à rẹ, èmi yóò sì sọ ohun tí òun bá wí fún ọ.”