1 Samuel 2:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Hana bá gbadura báyìí pé: “Ọkàn mi kún fún ayọ̀ ninu OLUWA, Ó sọ mí di alágbára; mò ń fi àwọn ọ̀tá mi rẹ́rìn-ín, nítorí mò ń yọ̀ pé OLUWA gbà mí là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
HANNA si gbadura pe, Ọkàn mi yọ̀ si Oluwa, iwo mi li a si gbe soke si Oluwa: ẹnu mi si gboro lori awọn ọta mi; nitoriti emi yọ̀ ni igbala rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Hánà sì gbàdúrà pé: “Ọkàn mi yọ̀ sí OLÚWA; Ìwọ agbára mi ni a sì gbé sókè sí OLÚWA. Ẹnu mi sì gbòòrò lórí àwọn ọ̀ta mi, nítorí ti èmi yọ̀ ni igbala rẹ̀