1 Samuel 2:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Elikana pada sí ilé rẹ̀ ní Rama. Ṣugbọn Samuẹli dúró sí Ṣilo, ó ń ṣiṣẹ́ iranṣẹ sin OLUWA, lábẹ́ alufaa Eli.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Elkana si lọ si Rama si ile rẹ̀. Ọmọ na si nṣe iranṣẹ fun Oluwa niwaju Eli alufa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Elikánà sì lọ sí Rámà sí ilé rẹ̀, Ọmọ náà sì ń ṣe ìráńṣẹ́ fún OLÚWA níwájú Élì àlùfáà.