1 Samuel 2:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó jẹ́ àṣà àwọn alufaa pé nígbà tí ẹnìkan bá wá rúbọ, iranṣẹ alufaa yóo wá, ti òun ti ọ̀pá irin oníga mẹta tí wọ́n fi ń yọ ẹran lọ́wọ́ rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bá ń se ẹran náà lọ́wọ́ lórí iná,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iṣe awọn alufa pẹlu awọn enia ni, nigbati ẹnikan ba ṣe irubọ, iranṣẹ alufa a de, nigbati ẹran na nho lori iná, ti on ti ọpa-ẹran oniga mẹta li ọwọ́ rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iṣẹ́ àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ènìyàn ni pé nígbà tí ẹnìkan bá ṣe ìrúbọ, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, nígbà tí ẹran náà bá ń hó lórí iná, pẹ̀lú ọ̀pá-ẹran náà oníga mẹ́ta ní ọwọ́ rẹ̀.