1 Samuel 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
yóo ti ọ̀pá irin náà bọ inú ìkòkò ẹran, gbogbo ẹran tí ó bá yọ jáde á jẹ́ ti alufaa. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe sí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n bá wá rúbọ ní Ṣilo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
On a si fi gun inu apẹ, tabi kẹtili tabi òdu, tabi ikokò, gbogbo eyi ti ọpa-ẹran oniga na ba mu wá oke, alufa a mu u fun ara rẹ̀. Bẹ̃ni nwọn nṣe si gbogbo Israeli ti o wá si ibẹ̀ ni Ṣilo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Òun a sì fi gún inú apẹ, tàbí Kẹ́tìlì tàbí òdù, tàbí ìkòkò, gbogbo èyí tí ọ̀pá-ẹran oníga náà bá mú wá sí òkè, àlùfáà á mú un fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì tí ó wá sí ibẹ̀ ní Ṣílò.