1 Samuel 2:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ati pé, kí wọ́n tilẹ̀ tó rẹ́ ọ̀rá tí wọ́n máa ń sun kúrò lára ẹran, iranṣẹ alufaa á wá, a sì wí fún ẹni tí ń rú ẹbọ pé kí ó fún òun ninu ẹran tí alufaa yóo sun jẹ, nítorí pé alufaa kò ní gba ẹran bíbọ̀ lọ́wọ́ olúwarẹ̀, àfi ẹran tútù.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlu ki nwọn ki o to sun ọra na, iranṣẹ alufa a de, a si wi fun ọkunrin ti on ṣe irubọ pe, Fi ẹran fun mi lati sun fun alufa; nitoriti kì yio gba ẹran sisè lọwọ rẹ, bikoṣe tutù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú, kí wọn tó sun ọ̀rá náà, ìráńṣẹ́ àlùfáà á dé, á sì wí fún ọkùnrin tí ó ń ṣe ìrúbọ pé, “Fi ẹran fún mi láti sun fún àlùfàá; nítorí tí kì yóò gba ẹran sísè lọ́wọ́ rẹ, bí kò se tútù.”