1 Samuel 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ẹni tí ń rú ẹbọ náà bá dá a lóhùn pé “Jẹ́ kí á kọ́kọ́ sun ọ̀rá ẹran náà, lẹ́yìn náà kí o wá mú ohun tí ó bá wù ọ́.” Iranṣẹ alufaa náà á wí pé, “Rárá! Nisinsinyii ni kí o fún mi, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo mú un tipátipá.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin na si wi fun u pe, Jẹ ki wọn sun ọra na nisisiyi, ki o si mu iyekiye ti ọkàn rẹ ba fẹ; nigbana li o da a lohun pe, Bẹ̃kọ, ṣugbọn ki iwọ ki o fi i fun mi nisisiyi: bikoṣe bẹ̃, emi o fi agbara gbà a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọkùnrin náà bá sì wí fún un pé, “Jẹ́ kí wọn ó sun ọ̀rá náà nísinsin yìí, kí o sì mú iyekíye tí ọkàn rẹ̀ bá fẹ́;” nígbà náà ni yóò dá a lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n kí ìwọ ó fi í fún mi nísinsin yìí, bí kó ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó fi agbára gbà á.”