1 Samuel 2:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Eli ti di arúgbó gan-an ní àkókò yìí. Ó ń gbọ́ gbogbo ohun tí àwọn ọmọ rẹ̀ ń ṣe sí àwọn ọmọ Israẹli, ati bí wọ́n ti ṣe ń bá àwọn obinrin tí wọn ń ṣiṣẹ́ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ lòpọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eli si di arugbo gidigidi, o si gbọ́ gbogbo eyi ti awọn ọmọ rẹ̀ ṣe si gbogbo Israeli; ati bi nwọn ti ima ba awọn obinrin sùn, ti nwọn ma pejọ li ẹnu ọ̀na agọ ajọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Élì sì di arúgbó gidigidi, ó sì gbọ́ gbogbo èyí ti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe sí gbogbo Ísírẹ́lì; àti bi wọ́n ti máa ń bá àwọn obìnrin sùn, tí wọ́n máa ń péjọ ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ.