1 Samuel 2:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Kí ló dé tí o fi ń ṣe ojúkòkòrò sí ọrẹ ati ẹbọ tí mo bèèrè lọ́wọ́ àwọn eniyan mi, tí o sì gbé àwọn ọmọ rẹ ga jù mí lọ; tí wọn ń jẹ àwọn ohun tí ó dára jùlọ lára ohun tí àwọn eniyan mi bá fi rúbọ sí mi ní àjẹyọkùn?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Eṣe ti ẹnyin fi tapa si ẹbọ ati ọrẹ mi, ti mo pa li aṣẹ ni ibujoko mi: iwọ si bu ọla fun awọn ọmọ rẹ jù mi lọ, ti ẹ si fi gbogbo ãyo ẹbọ Israeli awọn enia mi mu ara nyin sanra?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èé ha ṣe tí ẹ̀yin fi tàpá sí ẹbọ àti ọrẹ mi, tí mo páṣẹ ní ibùjókòó mi: ìwọ sì bu ọlá fún àwọn ọmọ rẹ jú mí lọ, tí ẹ sì fi gbogbo àṣàyàn ẹbọ Ísírẹ́lì àwọn ènìyàn mi mú ara yín sanra.’