1 Samuel 2:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, èmi OLUWA Ọlọrun Israẹli ni mo sọ pé, mo ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀ pé, ìdílé rẹ ati ìdílé baba rẹ ni yóo máa jẹ́ alufaa mi títí lae. Ṣugbọn nisinsinyii, èmi OLUWA náà ni mo sì tún ń sọ pé, kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́, nítorí pé àwọn tí wọ́n bá bu ọlá fún mi ni n óo máa bu ọlá fún, àwọn tí wọn kò bá kà mí sí, n kò ní ka àwọn náà sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina Oluwa Ọlọrun Israeli wipe, Emi ti wi nitotọ pe, ile rẹ ati ile baba rẹ, yio ma rin niwaju mi titi: ṣugbọn nisisiyi Oluwa wipe, ki a má ri i; awọn ti o bu ọla fun mi li emi o bu ọla fun, ati awọn ti kò kà mi si li a o si ṣe alaikasi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí pé, ‘Èmi ti wí nítòótọ́ pé, ilé rẹ àti ilé baba rẹ, yóò máa rìn níwájú mi títí.’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí OLÚWA wí pé, ‘Kí á má rí i! Àwọn tí ó bú ọlá fún mi ni èmi yóò bu ọlá fún, àti àwọn tí kò kà mí sí ni a ó sì ṣe aláìkàsí.