1 Samuel 2:33 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹnìkan ninu ìdílé rẹ tí n kò ní mú kúrò ní ibi pẹpẹ mi, yóo sọkún títí tí ojú rẹ̀ yóo fi di bàìbàì, ọkàn rẹ̀ yóo sì kún fún ìbànújẹ́. Gbogbo ọmọ inú ilé rẹ ni wọn yóo fi idà pa ní ọjọ́ àìpé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin ti iṣe tirẹ, ẹniti emi kì yio ke kuro ni ibi pẹpẹ mi, yio wà lati ma pọn ọ loju, lati ma bà ọ ninu jẹ; gbogbo iru ọmọ ile rẹ ni yio kú li abọ̀ ọjọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọkùnrin tí ó jẹ́ tìrẹ, tí èmi kì yóò gé kúrò ni ibi pẹpẹ mi ni a ó dá sí láti sunkún yọ lójú àti láti banújẹ́: Ṣùgbọ́n gbogbo irú-ọmọ ilé rẹ̀ ni a ó fi idà pa ní ààbọ̀ ọjọ́ wọn.