1 Samuel 2:36 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Èyíkéyìí tí ó bá wà láàyè ninu arọmọdọmọ rẹ yóo máa tọ alufaa yìí lọ láti tọrọ owó ati oúnjẹ lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ̀bẹ̀ ni yóo sì máa bẹ̀, pé kí ó fi òun sí ipò alufaa kí òun baà lè máa rí oúnjẹ jẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si ṣe, olukuluku ẹniti o ba kù ni ile rẹ yio wá tẹriba fun u nitori fadaka diẹ, ati nitori okele onjẹ, yio si wipe, Jọwọ fi mi sinu ọkan ninu iṣẹ awọn alufa, ki emi ki o le ma ri akara diẹ jẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà olúkúlùkù ẹnikẹ́ni tí ó bá kù ní ìdílé yín, yóò jáde wá yóò sì foríbalẹ̀ níwájú rẹ̀ nítorí ẹyọ fàdákà àti nítorí èépá àkàrà àti ẹ̀bẹ̀ pé, “Jọ̀wọ́ yàn mí sí ọ̀kan nínú iṣẹ́ àwọn àlùfáà, kí èmi kí ó le máa rí oúnjẹ jẹ.” ’ ”