1 Samuel 2:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ń gbé talaka dìde láti ipò ìrẹ̀lẹ̀; ó ń gbé aláìní dìde láti inú òṣì rẹ̀, láti mú wọn jókòó pẹlu àwọn ọmọ ọba, kí wọ́n sì wà ní ipò ọlá. Nítorí pé òun ni ó ni àwọn ìpìlẹ̀ ayé, òun ni ó sì gbé ayé kalẹ̀ lórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O gbe talaka soke lati inu erupẹ wá, o gbe alagbe soke lati ori ãtan wá, lati ko wọn jọ pẹlu awọn ọmọ-alade, lati mu wọn jogun itẹ ogo: nitori pe ọwọ̀n aiye ti Oluwa ni, o si ti gbe aiye ka ori wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó gbé tálákà sókè láti inú erùpẹ̀ wá, ó gbé alágbe sókè láti orí òkítì eérú wá, láti mú wọn jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé, láti mu wọn jogún ìtẹ́ ogo: “Nítorí pé ọ̀wọ̀n ayé ti OLÚWA ni, ó sì ti gbé ayé ka orí wọn