1 Samuel 20:1 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Dafidi sá kúrò ní Naioti, ní Rama, lọ sọ́dọ̀ Jonatani, ó sì bi í pé, “Kí ni mo ṣe? Ìwà burúkú wo ni mo hù? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ baba rẹ tí ó fi ń wọ́nà láti pa mí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
DAFIDI si sa kuro ni Naoti ti Rama, o si wá, o si wi li oju Jonatani pe, Kili emi ṣe? kini ìwa buburu mi, ati kili ẹ̀ṣẹ mi li oju baba rẹ, ti o fi nwá ọ̀na ati pa mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Dáfídì sá kúrò ní Naíótì ti Rámà ó sì lọ sọ́dọ̀ Jónátanì ó sì béèrè pé, “Kí ni mo ṣe? Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Báwo ni mo ṣe ṣẹ baba rẹ, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti gba ẹ̀mí mi?”