1 Samuel 20:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Kí OLUWA Ọlọrun Israẹli ṣe ẹlẹ́rìí láàrin èmi pẹlu rẹ. Ní àkókò yìí lọ́la tabi ní ọ̀tunla n óo wádìí nípa rẹ̀ lọ́wọ́ baba mi. Bí inú rẹ̀ bá yọ́ sí ọ n óo ranṣẹ sí ọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jonatani si wi fun Dafidi pe, Oluwa Ọlọrun Israeli, nigbati mo ba si lu baba mi li ohùn gbọ́ li ọla tabi li ọtunla, si wõ, bi ire ba wà fun Dafidi, ti emi kò ba si ranṣẹ si ọ, ti emi kò si sọ ọ li eti rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jónátanì sọ fún Dáfídì: “Pẹ̀lú OLÚWA Ọlọ́run àwọn Ísírẹ́lì, èmi yóò rí i dájú pé mo gbọ́ ti ẹnu baba mi ní ìwòyí ọ̀la tàbí ní ọ̀túnla tí ó bá sì ní ojú rere ní inú dídùn sí ọ, tí èmi kò bá ránṣẹ́ sí ọ, kí èmi sì jẹ́ kí o mọ̀?