1 Samuel 20:13 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ó bá ń gbèrò láti ṣe ọ́ níbi, kí OLUWA ṣe bẹ́ẹ̀ sí mi ati jù bẹ́ẹ̀ lọ, kí OLUWA pa mí bí n kò bá sọ fún ọ, kí n sì ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sá àsálà. Kí OLUWA wà pẹlu rẹ bí ó ti ṣe wà pẹlu baba mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃ ati ju bẹ̃ lọ si Jonatani: ṣugbọn bi o ba si ṣe pe o wu baba mi lati ṣe buburu si ọ, emi o si sọ ọ li eti rẹ, emi o si jẹ ki o lọ, iwọ o si lọ li alafia, ki Oluwa ki o si pẹlu rẹ gẹgẹ bi o ti wà pẹlu baba mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n tí baba mi kò bá ní ìfẹ́ sí pa ọ́ lára, kí OLÚWA kí ó dí ìyà jẹ mí, tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ; tí n kò bá jẹ́ kí o mọ̀, kí n sì jẹ́ kí o lọ ní àlàáfíà. Kí OLÚWA kí ó pẹ̀lú ù rẹ gẹ́gẹ́ bí ó ti wà pẹ̀lú baba mi.