1 Samuel 20:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà, Jonatani sọ fún Dafidi pé, “Ọ̀la ni ọjọ́ àjọ̀dún oṣù tuntun, àwọn eniyan yóo sì mọ̀ bí o kò bá wá síbi oúnjẹ nítorí ààyè rẹ yóo ṣófo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jonatani wi fun Dafidi pe, ọla li oṣu titun: a o si fẹ ọ kù, nitoriti ipò rẹ yio ṣofo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jónátanì wí fún Dáfídì pé, “Lọ́la ní ibi àsè ìbẹ̀rẹ̀ oṣù tuntun, a ó ò fẹ́ ọ kù, nítorí àyè rẹ yóò ṣófo.