1 Samuel 20:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí wọn kò bá rí ọ ní ọjọ́ keji, wọn yóo mọ̀ dájú pé o kò sí láàrin wọn. Nítorí náà, lọ sí ibi tí o farapamọ́ sí ní ìjelòó, kí o sì farapamọ́ sẹ́yìn àwọn òkúta ọ̀hún nnì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwọ ba si duro ni ijọ mẹta, nigbana ni iwọ o si yara sọkalẹ, iwọ o si wá si ibiti iwọ gbe ti fi ara rẹ pamọ si nigbati iṣẹ na wà lọwọ, iwọ o si joko ni ibi okuta Eseli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọ̀túnla lọ́wọ́ alẹ́ lọ sí bi tí o sá pamọ́ sí nígbà tí ìṣòro yìí bẹ̀rẹ̀, kí o sì dúró níbi òkúta Ésélù.