1 Samuel 20:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ní ọjọ́ keji àjọ̀dún oṣù tuntun, ìjókòó Dafidi tún ṣófo. Nígbà náà ni Saulu bèèrè lọ́wọ́ Jonatani pé, “Kí ló dé tí ọmọ Jese kò wá sí ibi oúnjẹ lánàá ati lónìí?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si ṣe, ni ijọ keji, ti o jẹ ijọ keji oṣu, ipò Dafidi si ṣofo; Saulu si wi fun Jonatani ọmọ rẹ̀ pe, Ẽṣe ti ọmọ Jesse ko fi wá si ibi onjẹ lana ati loni?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kejì, ní ọjọ́ kejì oṣù, ààyè Dáfídì sì tún ṣófo. Nígbà náà ni Ṣọ́ọ̀lù wí fún ọmọ rẹ̀ Jónátanì pé, “Kí ni ó dé tí ọmọ Jésè kò fi wá síbi oúnjẹ, lánàá àti lónìí?”