1 Samuel 20:29 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó sọ pé, àwọn ẹ̀gbọ́n òun ti pa á láṣẹ fún òun láti wá sí ibi àjọ̀dún ẹbọ ọdọọdún ti ìdílé wọn. Ó sì tọrọ ààyè lọ́wọ́ mi pé òun fẹ́ wà pẹlu àwọn ìdílé òun ní àkókò àjọ̀dún náà. Òun ni kò fi lè wá síbi àsè ọba.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Jọwọ, jẹ ki emi ki o lọ; nitoripe idile wa li ẹbọ kan iru ni ilu na; ẹgbọn mi si paṣẹ fun mi pe ki emi ki o má ṣaiwà nibẹ; njẹ, bi emi ba ri oju rere gbà lọdọ rẹ, jọwọ, jẹ ki emi lọ, ki emi ri awọn ẹgbọn mi. Nitorina ni ko ṣe wá si ibi onjẹ ọba.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, ‘Jẹ́ kí n lọ, nítorí pé ìdílé wa ń ṣe ìrúbọ ní ìlú, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀n mi sì ti pàṣẹ fún mi láti wà níbẹ̀; tí èmi bá rí ojú rere ní ojú rẹ, jẹ́ kí n lọ láti lọ rí àwọn ẹ̀gbọ́n mi.’ Ìdí nì yí tí kò fi wá sí orí tábìlì oúnjẹ ọba.”