1 Samuel 20:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Dafidi dáhùn pé, “Baba rẹ mọ̀ wí pé bí òun bá sọ fún ọ, inú rẹ kò ní dùn, nítorí pé o fẹ́ràn mi. Nítòótọ́ bí OLUWA tí ń bẹ láàyè, tí ẹ̀mí rẹ náà sì ń bẹ láàyè, ìṣísẹ̀ kan ló wà láàrin èmi ati ikú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Dafidi si tun bura, pe, Baba rẹ ti mọ̀ pe, emi ri oju rere li ọdọ rẹ; on si wipe, Máṣe jẹ ki Jonatani ki o mọ̀ nkan yi, ki o má ba binu: ṣugbọn nitotọ, bi Oluwa ti wà, ati bi ọkàn rẹ si ti wà lãye, iṣisẹ̀ kan ni mbẹ larin emi ati ikú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n Dáfídì tún búra, ó sì wí pé, “Baba rẹ mọ̀ dáradára pé mo rí ojú rere ní ojú ù rẹ, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, ‘Jónátanì kò gbọdọ̀ mọ èyí yóò sì bà á nínú jẹ́.’ Ṣíbẹ̀ nítòótọ́ bí OLÚWA ti wà láàyè àti gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wà láàyè, ìgbésẹ̀ kan ni ó wà láàrin èmi àti ikú.”