1 Samuel 20:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣé o kò mọ̀ wí pé níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jese bá wà láàyè, o kò lè jọba ní Israẹli kí ìjọba rẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀? Yára nisinsinyii kí o ranṣẹ lọ mú un wá; dandan ni kí ó kú.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe ni gbogbo ọjọ ti ọmọ Jesse wà lãye li orilẹ, iwọ ati ijọba rẹ kì yio duro. Njẹ nisisiyi, ranṣẹ ki o si mu u fun mi wá, nitoripe yio kú dandan.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níwọ̀n ìgbà tí ọmọ Jésè bá wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé, a kì yóò fi ẹṣẹ̀ ìwọ tàbí ti ìjọba rẹ múlẹ̀. Nísinsìn yìí ránṣẹ́ kí o sì lọ mú un wá fún mi, nítorí ó gbọ́dọ̀ kú!”